5. OLUWA ń yẹ àwọn olódodo, ati eniyan burúkú wò,ṣugbọn tọkàntọkàn ni ó kórìíra àwọn tí ó fẹ́ràn ìwà ipá.
6. Yóo rọ̀jò ẹ̀yinná ati imí ọjọ́ gbígbóná sórí àwọn eniyan burúkú;ìjì gbígbóná ni yóo sì jẹ́ ìpín wọn.
7. Nítorí olódodo ni OLUWA, ó sì fẹ́ràn òdodo;àwọn olóòótọ́ ni yóo rí ojú rẹ̀.