Orin Dafidi 109:3-6 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ káàkiri nípa mi,wọ́n sì ń gbógun tì mí láìnídìí.

4. Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí,sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn.

5. Ibi ni wọ́n fí ń san oore fún mi,ìkórìíra ni wọ́n sì fi ń san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn.

6. Yan eniyan burúkú tì í,jẹ́ kí ẹlẹ́sùn èké kó o sẹ́jọ́.

Orin Dafidi 109