Orin Dafidi 106:30-33 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn,àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró.

31. A sì kà á kún òdodo fún un,láti ìrandíran títí lae.

32. Wọ́n mú OLUWA bínú lẹ́bàá omi Meriba,wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mose,

33. nítorí wọ́n mú Mose bínú,ọ̀rọ̀ tí kò yẹ sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.

Orin Dafidi 106