Orin Dafidi 105:40-42 BIBELI MIMỌ (BM)

40. Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò,ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run.

41. Ó la àpáta, omi tú jáde,ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò.

42. Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀,ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀.

Orin Dafidi 105