39. OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n,ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru.
40. Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò,ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run.
41. Ó la àpáta, omi tú jáde,ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò.
42. Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀,ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀.
43. Ó fi ayọ̀ kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde,ó kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹlu orin.
44. Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà.
45. Kí wọ́n lè máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ,kí wọ́n sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́.Ẹ yin OLUWA!