14. Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan,nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà,kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san;nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé,ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba.
15. Ṣẹ́ eniyan burúkú ati aṣebi lápá,tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú rẹ̀,má sì jẹ́ kí ọ̀kan ninu wọn farasin.
16. OLUWA ni ọba lae ati laelae.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo pòórá lórí ilẹ̀ rẹ.
17. OLUWA, o óo gbọ́ igbe àwọn tí a nilára;o óo mú wọn lọ́kàn le,o óo sì dẹ etí sílẹ̀ sí igbe wọn
18. kí o lè ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn aláìníbabaati àwọn ẹni tí à ń pọ́n lójú,kí ọmọ eniyan, erùpẹ̀ lásánlàsàn, má lè dẹ́rù bani mọ́.