6. Mose bá gba àwọn ọkọ̀ ẹrù ati àwọn akọ mààlúù náà, ó kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi.
7. Ó fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ọkọ̀ ẹrù meji ati akọ mààlúù mẹrin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn.
8. Ó fún àwọn ọmọ Merari ní ọkọ̀ ẹrù mẹrin ati akọ mààlúù mẹjọ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn, lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni alufaa.
9. Ṣugbọn àwọn ọmọ Kohati ni Mose kò fún ní nǹkankan, nítorí pé àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n máa ń fi èjìká rù ni iṣẹ́ ìsìn wọn jẹ mọ́.
10. Àwọn olórí náà rú ẹbọ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ ní ọjọ́ tí wọ́n ta òróró sí i, láti yà á sí mímọ́. Wọ́n mú ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ.
11. OLUWA sọ fún Mose pé, “Kí olukuluku olórí mú ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ wá ní ọjọ́ tirẹ̀.”
12. Ní ọjọ́ kinni, Naṣoni ọmọ Aminadabu, olórí ẹ̀yà Juda mú ẹbọ tirẹ̀ wá.