Nọmba 31:39-47 BIBELI MIMỌ (BM)

39. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ́ ẹgbaa mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (30,500), ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ mọkanlelọgọta.

40. Àwọn eniyan sì jẹ́ ẹgbaajọ (16,000), ìpín ti OLUWA jẹ́ mejilelọgbọn.

41. Mose kó ìpín ti OLUWA fún Eleasari alufaa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

42. Ìdajì yòókù, tí ó jẹ́ ìpín àwọn ọmọ Israẹli tí kò lọ sójú ogun,

43. jẹ́ ẹgbaa mejidinlaadọsan-an ó lé ẹẹdẹgbẹjọ (337,500) aguntan.

44. Ẹgbaa mejidinlogun (36,000) mààlúù.

45. Ẹgbaa mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (30,500) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

46. Àwọn eniyan sì jẹ́ ẹgbaa mẹjọ (16,000).

47. Ninu wọn, Mose mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu araadọta ninu àwọn eniyan ati ẹranko, ó sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA, bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

Nọmba 31