15. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà lẹ́yìn èyí, ọkọ náà ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ obinrin náà nítorí pé kò jẹ́ kí ó san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.
16. Bẹ́ẹ̀ ni ìlànà tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose láàrin ọkọ ati aya ati láàrin baba ati ọmọ rẹ̀ obinrin, tí ń gbé ninu ilé rẹ̀.