20. “Ní ọjọ́ kẹta, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mọkanla, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.
21. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni;
22. pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
23. “Ní ọjọ́ kẹrin, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹ́wàá, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.
24. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni;
25. pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
26. “Ní ọjọ́ karun-un, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹsan-an, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.
27. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni,