4. Eleasari yóo gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn sí apá ìhà Àgọ́ Àjọ ní ìgbà meje.
5. Kí wọ́n sun ìyókù mààlúù náà: awọ rẹ̀ ati ẹran ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ati ìgbẹ́ rẹ̀; kí wọ́n sun gbogbo rẹ̀ níwájú alufaa.
6. Kí alufaa ju igi kedari ati hisopu ati aṣọ pupa sinu iná náà.
7. Lẹ́yìn náà kí ó wẹ̀, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì pada sí ibùdó. Ṣugbọn yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.
8. Ẹni tí ó sun mààlúù náà gbọdọ̀ wẹ̀ kí ó sì fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.
9. Ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo kó eérú mààlúù náà jọ sí ibìkan tí ó mọ́ lẹ́yìn ibùdó. Eérú náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóo máa lò fún omi ìwẹ̀nùmọ́, fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.
10. Ẹni tí ó bá kó eérú náà jọ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Èyí yóo jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli ati fún àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn títí lae.