11. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje.
12. Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, yóo wẹ ara rẹ̀ pẹlu omi ìwẹ̀nùmọ́, yóo sì di mímọ́. Kò ní di mímọ́ bí kò bá wẹ ara rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje.
13. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú, tí kò bá fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀, yóo sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin ọmọ Israẹli, nítorí kò fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀; ó sì jẹ́ aláìmọ́ sibẹ.
14. “Tí ẹnìkan bá kú ninu àgọ́ kan ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ninu àgọ́ náà, ati ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ibẹ̀ yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje.
15. Gbogbo ohun èlò tí ó bá wà ninu àgọ́ náà tí wọn kò fi ọmọrí dé di aláìmọ́.
16. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n fi idà pa, tabi òkú, tabi egungun òkú tabi ibojì òkú ninu pápá yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje.
17. “Tí ẹ bá fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ wọn, ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo mú lára eérú mààlúù pupa tí a sun fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo bu omi odò tí ń ṣàn sí i.
18. Lẹ́yìn náà yóo mú hisopu, yóo tì í bọ omi náà, yóo sì fi wọ́n àgọ́ náà ati àwọn ohun èlò tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Yóo fi wọ́n ẹni tí ó fọwọ́ kan egungun òkú tabi tí ó fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n pa, tabi ẹni tí ó kú fúnrarẹ̀, tabi ibojì òkú.