Nọmba 16:47-50 BIBELI MIMỌ (BM)

47. Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Mose. Ó mú àwo turari rẹ̀, ó sáré lọ sí ààrin àwọn eniyan náà. Nígbà tí ó rí i pé àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ́ sílẹ̀, ó fi turari sí i, ó sì ṣe ètùtù fún wọn.

48. Aaroni dúró ní ààrin àwọn òkú ati alààyè, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì dáwọ́ dúró.

49. Àwọn tí ó kú jẹ́ ẹgbaa meje ó lé ẹẹdẹgbẹrin (14,700) láìka àwọn tí ó kú pẹlu Kora.

50. Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn náà dáwọ́ dúró, Aaroni pada sọ́dọ̀ Mose lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

Nọmba 16