Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Mose. Ó mú àwo turari rẹ̀, ó sáré lọ sí ààrin àwọn eniyan náà. Nígbà tí ó rí i pé àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ́ sílẹ̀, ó fi turari sí i, ó sì ṣe ètùtù fún wọn.