11. láti inú ẹ̀yà Josẹfu, tí í ṣe ẹ̀yà Manase, ó rán Gadi, ọmọ Susi;
12. láti inú ẹ̀yà Dani, ó rán Amieli, ọmọ Gemali;
13. láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ó rán Seturu, ọmọ Mikaeli;
14. láti inú ẹ̀yà Nafutali, ó rán Nahibi ọmọ Fofisi;
15. láti inú ẹ̀yà Gadi, ó rán Geueli ọmọ Maki.
16. Orúkọ àwọn ọkunrin tí Mose rán láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà nìyí. Mose sì yí orúkọ Hoṣea ọmọ Nuni pada sí Joṣua.