1. Nígbà tí ó yá àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí OLUWA nípa ìṣòro wọn. Nígbà tí OLUWA gbọ́ kíkùn wọn, inú bí i, ó sì fi iná jó wọn; iná náà run gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní òpin ibùdó náà.
2. Àwọn eniyan náà sì ké tọ Mose wá fún ìrànlọ́wọ́. Mose gbadura fún wọn, iná náà sì kú.
3. Wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Tabera, nítorí níbẹ̀ ni iná OLUWA ti jó láàrin wọn.
4. Àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn, pé àwọn kò rí ẹran jẹ bí ìgbà tí àwọn wà ní Ijipti. Àwọn ọmọ Israẹli pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún àìrẹ́ran jẹ. Wọ́n ń sọ pé, “Ó mà ṣe o, a kò rí ẹran jẹ!
5. Ní Ijipti, à ń jẹ ẹja ati apálà, ẹ̀gúsí, ewébẹ̀, alubọsa ati galiki.
6. Ṣugbọn nisinsinyii, a kò lókun ninu mọ́, kò sí ohun tí a rí jẹ bíkòṣe mana yìí nìkan lojoojumọ.”
7. Mana náà sì dàbí èso korianda, tí àwọ̀ rẹ̀ dàbí kóró òkúta bideliumi.
8. Àwọn eniyan náà a máa lọ kó wọn láàárọ̀, wọn á lọ̀ ọ́ tabi kí wọn gún un lódó láti fi ṣe ìyẹ̀fun. Wọn á sè é ninu ìkòkò, wọn á fi ṣe bíi àkàrà, adùn rẹ̀ sì dàbí ti àkàrà dídùn tí a fi òróró olifi dín.