Nọmba 10:10-17 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ẹ óo máa fọn àwọn fèrè náà ní ọjọ́ ayọ̀, ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín ati ní ọjọ́ kinni oṣù. Ẹ óo máa fọn wọ́n nígbà tí ẹ bá mú ọrẹ ẹbọ sísun ati ọrẹ ẹbọ alaafia yín wá fún Ọlọrun. Yóo jẹ́ àmì ìrántí fun yín níwájú Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

11. Ní ogúnjọ́ oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, ìkùukùu tí ó wà ní orí ibi mímọ́ gbéra sókè.

12. Àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn láti aṣálẹ̀ Sinai, wọ́n tò lẹ́sẹẹsẹ. Ìkùukùu náà bá dúró ní aṣálẹ̀ Parani.

13. Ìgbà kinni nìyí tí wọn yóo tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa láti ẹnu Mose.

14. Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Juda ni wọ́n kọ́kọ́ ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Naṣoni ọmọ Aminadabu ni olórí wọn.

15. Netaneli ọmọ Suari ni olórí ẹ̀yà Isakari.

16. Olórí ẹ̀yà Sebuluni sì ni Eliabu ọmọ Heloni.

17. Nígbà tí wọ́n tú Àgọ́ Àjọ palẹ̀, àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari tí ó ru Àgọ́ Àjọ náà ṣí tẹ̀lé àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Juda.

Nọmba 10