33. jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).
34. Ninu ẹ̀yà Manase, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
35. jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun ó lé igba (32,200).
36. Ninu ẹ̀yà Bẹnjamini, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
37. jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogun ó lé egbeje (35,400).
38. Ninu ẹ̀yà Dani, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
39. jẹ́ ẹgbaa mọkanlelọgbọn ó lé ẹẹdẹgbẹrin (62,700).
40. Ninu ẹ̀yà Aṣeri, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
41. jẹ́ ọ̀kẹ́ meji le ẹẹdẹgbẹjọ (41,500).