16. Àwọn eniyan náà jáde, wọ́n sì lọ wá imọ̀ ọ̀pẹ ati ẹ̀ka igi wá, wọ́n sì pàgọ́ fún ara wọn, kaluku pàgọ́ sí orí ilé, ati sí àgbàlá ilé wọn ati sí àgbàlá ilé Ọlọrun pẹlu, wọ́n pàgọ́ sí ìta Ẹnubodè Omi ati sí ìta Ẹnubodè Efuraimu.
17. Gbogbo àpéjọ àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú pa àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn. Láti ìgbà ayé Joṣua ọmọ Nuni, títí di àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kò pàgọ́ bẹ́ẹ̀ rí, gbogbo wọn sì yọ ayọ̀ ńlá.
18. Lojoojumọ, láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ tí àsè náà parí, ni wọ́n ń kà ninu ìwé òfin. Wọ́n ṣe àjọ̀dún àsè náà fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n pe àpéjọ tí ó lọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí ó wà ninu àkọsílẹ̀.