23. Lẹ́yìn wọn ni Bẹnjamini ati Haṣubu ṣe àtúnṣe apá ibi tí ó kọjú sí ilé wọn. Lẹ́yìn wọn, Asaraya ọmọ Maaseaya, ọmọ Ananaya ṣe àtúnṣe ní ẹ̀gbẹ́ ilé tirẹ̀.
24. Lẹ́yìn rẹ̀, Binui, ọmọ Henadadi ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀: láti ilé Asaraya títí dé ibi Igun Odi.
25. Palali, ọmọ Usai ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí Igun Odi ati ilé ìṣọ́, láti òkè ilé ọba níbi ọgbà àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Pedaaya, ọmọ Paroṣi,
26. ati àwọn iranṣẹ tẹmpili tí wọn ń gbé Ofeli ṣe àtúnṣe tiwọn dé ibi tí ó kọjú sí Ẹnubodè Omi, ní ìhà ìlà oòrùn ati ilé ìṣọ́ tí ó yọgun jáde títí dé ibi odi Ofeli.
27. Lẹ́yìn náà ni àwọn ará Tekoa ṣe àtúnṣe apá ibi tí ó kọjú sí ilé ìṣọ́ tí ó yọgun jáde títí dé Ofeli.
28. Àwọn alufaa ni wọ́n tún Òkè Ẹnubodè Ẹṣin ṣe, olukuluku tún ibi tí ó kọjú sí ilé rẹ̀ ṣe.