7. A tú ayaba sí ìhòòhò,a sì mú un lọ sí ìgbèkùn,àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ń dárò rẹ̀,wọ́n káwọ́ lérí,wọ́n ń rin bí oriri.
8. Ìlú Ninefe dàbí adágún odòtí omi rẹ̀ ti ṣàn lọ.Wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ dúró! Ẹ dúró!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yíjú pada.
9. Ẹ kó fadaka,ẹ kó wúrà!Ìlú náà kún fún ìṣúra,ati àwọn nǹkan olówó iyebíye.
10. A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro!Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú,orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀,ìrora dé bá ọpọlọpọ,gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.
11. Níbo ni ìlú tí ó dàbí ihò àwọn kinniun wà?Tí ó rí bí ibùgbé àwọn ọ̀dọ́ kinniun?Ibi tí kinniun ń gbé oúnjẹ rẹ̀ lọ,tí àwọn ọmọ rẹ̀ wà,tí kò sí ẹni tí ó lè dà wọ́n láàmú?