Nahumu 2:2-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. (Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu padabí ògo Israẹli,nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn,wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.)

3. Pupa ni asà àwọn akọni rẹ̀,ẹ̀wù pupa ni àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀Kẹ̀kẹ́ ogun wọn ń kọ mànàbí ọwọ́ iná;nígbà tí wọ́n tò wọ́n jọ,àwọn ẹṣin wọn ń yan.

4. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo,wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede;wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù,wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná.

5. Ó pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jọ,wọ́n sì ń fẹsẹ̀ kọ bí wọ́n ti ń lọ,wọ́n yára lọ sí ibi odi,wọ́n sì fi asà dira ogun.

6. Àwọn ìlẹ̀kùn odò ṣí sílẹ̀,ìdàrúdàpọ̀ wà láàfin.

7. A tú ayaba sí ìhòòhò,a sì mú un lọ sí ìgbèkùn,àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ń dárò rẹ̀,wọ́n káwọ́ lérí,wọ́n ń rin bí oriri.

8. Ìlú Ninefe dàbí adágún odòtí omi rẹ̀ ti ṣàn lọ.Wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ dúró! Ẹ dúró!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yíjú pada.

9. Ẹ kó fadaka,ẹ kó wúrà!Ìlú náà kún fún ìṣúra,ati àwọn nǹkan olówó iyebíye.

Nahumu 2