10. Ẹ̀yin tí ẹ fi owó ẹ̀jẹ̀ kọ́ Sioni, tí ẹ sì fi èrè ìwà burúkú kọ́ Jerusalẹmu.
11. Àwọn aláṣẹ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó ṣe ìdájọ́, àwọn alufaa ń gba owó iṣẹ́ wọn kí wọ́n tó kọ́ni, àwọn wolii ń gba owó kí wọ́n tó ríran; sibẹsibẹ, wọ́n gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, wọ́n ń wí pé, “Ṣebí OLUWA wà pẹlu wa? Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí wa.”
12. Nítorí náà, nítorí yín, a óo ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóo di àlàpà, ahoro tẹmpili yóo sì di igbó kìjikìji.