Mika 2:7-11 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ṣé irú ọ̀rọ̀ tí eniyan máa sọ nìyí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu? Ṣé OLUWA kò ní mú sùúrù mọ́ ni? Àbí ẹ rò pé òun ni ó ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi? Àbí ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe àwọn tí wọ́n bá ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́ ní rere?”

8. OLUWA ní: “Ṣugbọn ẹ dìde sí àwọn eniyan mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá, ẹ gba ẹ̀wù lọ́rùn àwọn tí wọn ń lọ lalaafia, àwọn tí wọn ń rékọjá lọ láìronú ogun.

9. Ẹ lé àwọn aya àwọn eniyan mi jáde kúrò ninu ilé tí wọ́n fẹ́ràn; ẹ sì gba ògo mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn títí lae.

10. Ẹ dìde, ẹ máa lọ, nítorí pé ìhín yìí kì í ṣe ibi ìsinmi; nítorí pé ẹ ti hùwà ìríra tí ń mú ìparun ńlá báni.

11. “Wolii tí yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ati ẹ̀tàn ni àwọn eniyan wọnyi ń fẹ́, tí yóo sì máa waasu pé, ‘Ẹ óo ní ọpọlọpọ waini ati ọtí líle.’

Mika 2