4. Àwọn òkè ńlá yóo yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, bí ìda tíí yọ̀ níwájú iná;àwọn àfonífojì yóo pínyàgẹ́gẹ́ bí omi tí a dà sílẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.
5. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati ti ilé Israẹli ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣe ṣẹlẹ̀. Kí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu? Ṣebí ìlú Samaria ni. Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda? Ṣebí ìlú Jerusalẹmu ni.
6. OLUWA ní, “Nítorí náà, n óo sọ Samaria di àlàpà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, yóo di ọgbà ìgbin àjàrà sí; gbogbo òkúta tí a fi kọ́ ọ ni n óo fọ́nká, sinu àfonífojì, ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo sì hàn síta.
7. Gbogbo ère oriṣa rẹ̀ ni a óo fọ́ túútúú, a óo sì jó gbogbo owó iṣẹ́ àgbèrè rẹ̀ níná. Gbogbo ère rẹ̀ ni n óo kójọ bí òkítì, a óo sì kọ̀ wọ́n tì; nítorí pé owó àgbèrè ni ó fi kó wọn jọ, ọrọ̀ rẹ̀ yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a ṣe àgbèrè.
8. “Nítorí èyí, n óo sọkún, n óo sì pohùnréré ẹkún; n óo rìn káàkiri ní ìhòòhò láìwọ bàtà. N óo máa ké kiri bí ọ̀fàfà, n óo sì ṣọ̀fọ̀ bí ẹyẹ ògòǹgò.
9. Nítorí pé egbò Samaria kò lè ṣe é wò jinná; egbò náà sì ti ran Juda, ó ti dé ẹnubodè àwọn eniyan mi, àní, Jerusalẹmu.”