Matiu 7:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ṣugbọn ọ̀nà ìyè há, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fún. Díẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n rí i.

15. “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn wolii èké tí wọn máa ń wá sọ́dọ̀ yín. Ní òde, wọ́n dàbí aguntan, ṣugbọn ninu, ìkookò tí ó ya ẹhànnà ni wọ́n.

16. Nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n. Kò sí ẹni tí ó lè ká èso àjàrà lórí igi ẹ̀wọ̀n agogo tabi kí ó rí èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹ̀gún ọ̀gàn.

17. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni: gbogbo igi tí ó bá dára a máa so èso tí ó dára; igi tí kò bá dára a máa so èso burúkú.

18. Igi tí ó bá dára kò lè so èso burúkú; bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lè so èso rere.

19. Igikígi tí kò bá so èso rere, gígé ni a óo gé e lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.

20. Nítorí náà nípa èso wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n.

21. “Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa’ ni yóo wọ ìjọba ọ̀run, bíkòṣe àwọn tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.

22. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wí fún mi ní ọjọ́ ìdájọ́ pé, ‘Oluwa, Oluwa, a kéde ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní orúkọ rẹ; a lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ; a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ rẹ.’

23. Ṣugbọn n óo wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi wọnyi!’

Matiu 7