Matiu 4:6-12 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ,kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà ọ́,kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ”

7. Jesu sọ fún un pé, “Ó tún wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”

8. Èṣù tún mú un lọ sórí òkè gíga kan; ó fi gbogbo àwọn ìjọba ayé ati ògo wọn hàn án.

9. Ó bá sọ fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọnyi ni n óo fún ọ bí o bá wolẹ̀ tí o júbà mi.”

10. Jesu bá dá a lóhùn, ó ní, “Pada kúrò lẹ́yìn mi, Satani. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o máa sìn.’ ”

11. Lẹ́yìn náà, Èṣù fi í sílẹ̀. Àwọn angẹli bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń ṣe iranṣẹ fún un.

12. Nígbà tí Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ju Johanu sẹ́wọ̀n, ó yẹra lọ sí Galili.

Matiu 4