31. Nígbà náà Jesu sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi ní alẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan,gbogbo agbo aguntan ni a óo fọ́nká!’
32. “Ṣugbọn lẹ́yìn tí a bá ti jí mi dìde, n óo ṣiwaju yín lọ sí Galili.”
33. Peteru dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo àwọn yòókù bá tilẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ, bíi tèmi kọ́!”
34. Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé ní alẹ́ yìí, kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”
35. Peteru sọ fún un pé, “Bí mo bá tilẹ̀ níláti bá ọ kú, n kò ní sẹ́ ọ.”Bákan náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ.
36. Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ Gẹtisemani. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín, èmi ń lọ gbadura lọ́hùn-ún nì.”