Matiu 22:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Nígbà tí ọba wọlé láti wo àwọn tí wọn ń jẹun, ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí kò wọ aṣọ igbeyawo.

12. Ọba bi í pé, ‘Arakunrin, báwo ni o ti ṣe wọ ìhín láì ní aṣọ igbeyawo?’ Ṣugbọn kẹ́kẹ́ pamọ́ ọkunrin náà lẹ́nu.

13. Ọba bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́-tẹsẹ̀, kí ẹ sọ ọ́ sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’

14. “Nítorí ọpọlọpọ ni a pè, ṣugbọn àwọn díẹ̀ ni a yàn.”

15. Àwọn Farisi bá lọ forí-korí wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ Jesu lẹ́nu.

16. Wọ́n bá rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hẹrọdu láti bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ati pé pẹlu òtítọ́ ni o fi ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun; o kì í ṣe ojuṣaaju fún ẹnikẹ́ni nítorí o kì í wojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀.

17. Nítorí náà sọ ohun tí o rò fún wa. Ó tọ̀nà láti san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?”

Matiu 22