Matiu 22:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jesu tún fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀. Ó ní,

2. “Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan, tí ó ń gbeyawo fún ọmọ rẹ̀.

3. Ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ lọ pe àwọn tí ó dájọ́ igbeyawo náà fún, ṣugbọn wọn kò fẹ́ wá.

4. Ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn, kí wọ́n sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Mo ti se àsè tán; mo ti pa mààlúù ati àwọn ẹran ọlọ́ràá; mo ti ṣe ètò gbogbo tán. Ẹ wá sí ibi igbeyawo.’

5. Ṣugbọn wọn kò bìkítà. Ọ̀kan lọ sí oko rẹ̀, òmíràn lọ sí ìdí òwò rẹ̀.

Matiu 22