Ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn, kí wọ́n sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Mo ti se àsè tán; mo ti pa mààlúù ati àwọn ẹran ọlọ́ràá; mo ti ṣe ètò gbogbo tán. Ẹ wá sí ibi igbeyawo.’