11. Bí wọ́n ti wọlé, wọ́n rí ọmọ náà pẹlu Maria ìyá rẹ̀, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì júbà rẹ̀. Wọ́n ṣí àpótí ìṣúra wọn, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn: wúrà, turari ati òjíá.
12. Nítorí pé Ọlọrun ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ ní ojú àlá, wọn kò pada sọ́dọ̀ Hẹrọdu mọ́; ọ̀nà mìíràn ni wọ́n gbà pada lọ sí ìlú wọn.
13. Lẹ́yìn tí àwọn amòye ti pada lọ, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá, ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, kí o sálọ sí Ijipti, kí o sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí mo bá sọ fún ọ, nítorí Hẹrọdu yóo máa wá ọmọ náà láti pa á.”
14. Josẹfu bá dìde ní òru, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Ijipti.
15. Níbẹ̀ ni ó wà títí Hẹrọdu fi kú. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àsọtẹ́lẹ̀ nì lè ṣẹ pé, “Láti Ijipti ni mo ti pe ọmọ mi.”
16. Nígbà tí Hẹrọdu rí i pé àwọn amòye tan òun jẹ ni, inú bí i pupọ. Ó bá pàṣẹ pé kí wọn máa pa gbogbo àwọn ọmọ-ọwọ́ lọkunrin ní Bẹtilẹhẹmu ati ní gbogbo agbègbè ibẹ̀ láti ọmọ ọdún meji wálẹ̀ títí di ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, gẹ́gẹ́ bí àkókò tí ó fọgbọ́n wádìí lọ́wọ́ àwọn amòye.
17. Èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí wolii Jeremaya sọ lè ṣẹ pé,
18. “A gbọ́ ohùn kan ní Rama,ẹkún ati ọ̀fọ̀ gidi.Rakẹli ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀;ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀,nítorí wọn kò sí mọ́.”
19. Lẹ́yìn tí Hẹrọdu ti kú, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá ní Ijipti.