17. Kò ye yín pé ikùn ni gbogbo ohun tí eniyan bá fi sí ẹnu ń lọ ati pé eniyan óo tún yà á jáde?
18. Ṣugbọn ohun tí eniyan bá sọ láti inú ọkàn rẹ̀ wá, èyí ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.
19. Nítorí láti inú ọkàn ni èrò burúkú ti ń jáde wá: ìpànìyàn, àgbèrè, ìṣekúṣe, olè jíjà, ìjẹ́rìí èké, ìsọkúsọ.
20. Àwọn nǹkan wọnyi ni wọ́n ń sọ eniyan di aláìmọ́; kí eniyan jẹun láì wẹ ọwọ́ kò lè sọ eniyan di aláìmọ́.”
21. Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Tire ati Sidoni.
22. Obinrin Kenaani kan tí ó ń gbé ibẹ̀ bá jáde, ó ń kígbe pé, “Ṣàánú mi, Oluwa, ọmọ Dafidi. Ẹ̀mí èṣù ní ń da ọdọmọbinrin mi láàmú.”
23. Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá wá sọ fún un pé, “Lé obinrin yìí lọ, nítorí ó ń pariwo tẹ̀lé wa lẹ́yìn.”
24. Jesu bá dáhùn pé, “Kìkì àwọn aguntan tí ó sọnù, àní ìdílé Israẹli nìkan ni a rán mi sí.”
25. Ṣugbọn obinrin náà wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ràn mí lọ́wọ́.”
26. Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Kò dára láti sọ oúnjẹ ọmọ eniyan sóde sí àwọn ajá!”
27. Obinrin náà ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa. Ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti inú àwo oúnjẹ oluwa wọn.”
28. Nígbà náà ni Jesu sọ fún un pé, “Obinrin yìí! Igbagbọ rẹ tóbi gidi. Kí ó rí fún ọ bí o ti fẹ́.” Ara ọdọmọbinrin rẹ̀ bá dá láti àkókò náà.
29. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ẹ̀bá òkun Galili; ó gun orí òkè lọ, ó bá jókòó níbẹ̀.