1. Ní àkókò náà, Hẹrọdu ọba gbúròó Jesu.
2. Ó wí fún àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni èyí. Òun ni ó jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ó fi ní agbára láti lè ṣe iṣẹ́ ìyanu.”
3. Nítorí Hẹrọdu yìí ni ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú Johanu, kí wọ́n dè é, kí wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin Hẹrọdu.
4. Nítorí Johanu sọ fún Hẹrọdu pé kò tọ́ fún un láti fi Hẹrọdiasi ṣaya.
5. Hẹrọdu fẹ́ pa á, ṣugbọn ó bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí wọ́n gbà pé wolii ni Johanu.
6. Nígbà tí Hẹrọdu ń ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀, ọdọmọbinrin Hẹrọdiasi bẹ̀rẹ̀ sí jó lójú agbo. Èyí dùn mọ́ Hẹrọdu ninu
7. tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkohun tí ó bá bèèrè.
8. Lẹ́yìn tí ìyá ọmọbinrin yìí ti kọ́ ọ ní ohun tí yóo bèèrè, ó ní, “Gbé orí Johanu Onítẹ̀bọmi wá fún mi nisinsinyii ninu àwo pẹrẹsẹ kan.”
9. Ó dun ọba, ṣugbọn nítorí pé ó ti búra, ati nítorí àwọn tí ó wà níbi àsè, ó gbà láti fi fún un.
10. Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ Johanu lórí ninu ẹ̀wọ̀n tí ó wá.