45. “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ọkunrin oníṣòwò kan tí ó ń wá ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye kan.
46. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó dára pupọ, ó lọ ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá rà á.
47. “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí àwọ̀n tí a dà sinu òkun, tí ó kó oríṣìíríṣìí ẹja.
48. Nígbà tí ó kún, wọ́n fà á lọ sí èbúté, wọ́n jókòó, wọ́n ṣa àwọn ẹja tí ó dára jọ sinu garawa, wọ́n sì da àwọn tí kò wúlò nù.
49. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóo wá, wọn óo yanjú àwọn eniyan burúkú kúrò láàrin àwọn olódodo,
50. wọn yóo jù wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.”
51. Jesu bi wọ́n pé, “Ṣé gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ye yín?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”
52. Ó wá sọ fún wọn pé, “Nítorí èyí ni amòfin tí ó bá ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí baálé ilé kan, tí ó ń mú nǹkan titun ati nǹkan àtijọ́ jáde láti inú àpò ìṣúra rẹ̀.”
53. Lẹ́yìn tí Jesu ti parí gbogbo àwọn òwe wọnyi, ó kúrò níbẹ̀.