26. “Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù àwọn eniyan. Kò sí ohun tí ó wà ní ìpamọ́, tí kò ní fara hàn. Kò sì sí ohun àṣírí tí a kò ní mọ̀.
27. Ohun tí mo sọ fun yín níkọ̀kọ̀, ẹ sọ ọ́ ní gbangba. Ohun tí wọ́n yọ́ sọ fun yín, ẹ kéde rẹ̀ lórí òrùlé.
28. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara yín, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí yín. Ẹni tí ó yẹ kí ẹ bẹ̀rù ni Ọlọrun tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì.
29. Ṣebí meji kọbọ ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́! Sibẹ ọ̀kan ninu wọn kò lè jábọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn Baba yín.
30. Gbogbo irun orí yín ni ó níye.
31. Nítorí náà ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.
32. “Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.