12. Bí ó bá sì jẹ́ pé obinrin ni ó kọ ọkọ rẹ̀, tí ó fẹ́ ọkọ mìíràn, òun náà ṣe àgbèrè.”
13. Àwọn kan gbé àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí.
14. Nígbà tí Jesu rí i inú bí i: ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.
15. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọmọde, kò ní wọ ìjọba ọ̀run.”
16. Nígbà náà ni Jesu gbé àwọn ọmọde náà lọ́wọ́, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì súre fún wọn.
17. Nígbà tí Jesu jáde, bí ó ti ń lọ lọ́nà, ọkunrin kan sáré tọ̀ ọ́ lọ, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bi í pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”
18. Ṣugbọn Jesu wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan, àfi Ọlọrun nìkan.
19. Ṣé o mọ àwọn òfin: má paniyan, má ṣe àgbèrè, má jalè, má jẹ́rìí èké, má rẹ́nijẹ, bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ?”
20. Ọkunrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin ni mo ti ń pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́.”