Maku 1:9-14 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ní ọjọ́ kan, Jesu wá láti Nasarẹti ìlú kan ní Galili, Johanu bá ṣe ìrìbọmi fún un ninu odò Jọdani.

10. Bí Jesu ti ń jáde kúrò ninu omi, lẹ́sẹ̀ kan náà ó rí Ẹ̀mí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí àdàbà tí ó bà lé e.

11. Ó sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi, inú mi dùn sí ọ gidigidi.”

12. Lẹ́yìn èyí, Ẹ̀mí Ọlọrun gbé Jesu lọ sinu aṣálẹ̀.

13. Ó wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tí Satani ń dán an wò. Ààrin àwọn ẹranko ni ó wà, ṣugbọn àwọn angẹli ń ṣe iranṣẹ fún un.

14. Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ju Johanu sinu ẹ̀wọ̀n, Jesu wá sí Galili, ó ń waasu ìyìn rere tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá.

Maku 1