48. Ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọde yìí ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Nítorí ẹni tí ó kéré jùlọ ninu yín, òun ló jẹ́ eniyan pataki jùlọ.”
49. Johanu sọ fún un pé, “Ọ̀gá, a rí ẹnìkan tí ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. A fẹ́ dá a lẹ́kun nítorí kì í ṣe ara wa.”
50. Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé. “Ẹ má dá a lẹ́kun, nítorí ẹni tí kò bá lòdì si yín, tiyín ní ń ṣe.”
51. Nígbà tí ó tó àkókò tí a óo gbé Jesu lọ sókè ọ̀run, ọkàn rẹ̀ mú un láti lọ sí Jerusalẹmu.
52. Ó bá rán àwọn oníṣẹ́ ṣiwaju rẹ̀. Wọ́n bá wọ inú ìletò àwọn ará Samaria kan láti ṣe ètò sílẹ̀ dè é.
53. Ṣugbọn wọn kò gbà á, nítorí ó hàn dájú pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu.
54. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé o fẹ́ kí á pe iná láti ọ̀run kí ó jó wọn pa?”
55. Ṣugbọn Jesu yipada, ó bá wọn wí.
56. Ni wọ́n bá lọ sí ìletò mìíràn.
57. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “N óo máa bá ọ lọ sí ibikíbi tí o bá ń lọ.”
58. Jesu dá a lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.”
59. Ó bá sọ fún ẹlòmíràn pé, “Máa tẹ̀lé mi.”Ṣugbọn onítọ̀hún dáhùn pé, “Alàgbà, jẹ́ kí n kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.”