Luku 9:45-56 BIBELI MIMỌ (BM)

45. Ṣugbọn gbolohun yìí kò yé wọn, nítorí a ti fi ìtumọ̀ rẹ̀ pamọ́ fún wọn, kí ó má baà yé wọn. Ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí.

46. Àríyànjiyàn kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lórí pé ta ló ṣe pataki jùlọ láàrin wọn.

47. Jesu mọ ohun tí wọn ń rò lọ́kàn. Ó bá mú ọmọde kan, ó gbé e dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

48. Ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọde yìí ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Nítorí ẹni tí ó kéré jùlọ ninu yín, òun ló jẹ́ eniyan pataki jùlọ.”

49. Johanu sọ fún un pé, “Ọ̀gá, a rí ẹnìkan tí ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. A fẹ́ dá a lẹ́kun nítorí kì í ṣe ara wa.”

50. Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé. “Ẹ má dá a lẹ́kun, nítorí ẹni tí kò bá lòdì si yín, tiyín ní ń ṣe.”

51. Nígbà tí ó tó àkókò tí a óo gbé Jesu lọ sókè ọ̀run, ọkàn rẹ̀ mú un láti lọ sí Jerusalẹmu.

52. Ó bá rán àwọn oníṣẹ́ ṣiwaju rẹ̀. Wọ́n bá wọ inú ìletò àwọn ará Samaria kan láti ṣe ètò sílẹ̀ dè é.

53. Ṣugbọn wọn kò gbà á, nítorí ó hàn dájú pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu.

54. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé o fẹ́ kí á pe iná láti ọ̀run kí ó jó wọn pa?”

55. Ṣugbọn Jesu yipada, ó bá wọn wí.

56. Ni wọ́n bá lọ sí ìletò mìíràn.

Luku 9