Luku 9:37-50 BIBELI MIMỌ (BM)

37. Ní ọjọ́ keji, lẹ́yìn tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ eniyan wá pàdé rẹ̀.

38. Ọkunrin kan ninu àwùjọ kígbe pé, “Olùkọ́ni, mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú ọmọ mi, nítorí òun nìkan ni mo bí.

39. Ẹ̀mí kan a máa gbé e. Lójijì yóo kígbe tòò, ara rẹ̀ óo le gbandi. Yóo bá máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, ni ẹ̀mí yìí yóo bá gbé e ṣánlẹ̀; kò sì ní tètè fi í sílẹ̀.

40. Mo bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n lé e jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.”

41. Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran oníbàjẹ́ ati alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó! N óo ti fara dà á fun yín tó! Mú ọmọ rẹ wá síhìn-ín.”

42. Bí ó ti ń mú un bọ̀, ẹ̀mí èṣù yìí bá gbé e ṣánlẹ̀, wárápá bá mú un. Jesu bá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó bá fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.

43. Ẹnu ya gbogbo eniyan sí iṣẹ́ ńlá Ọlọrun.Bí ẹnu ti ń ya gbogbo eniyan sí gbogbo ohun tí Jesu ń ṣe, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

44. “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi wọ̀ yín létí. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́.”

45. Ṣugbọn gbolohun yìí kò yé wọn, nítorí a ti fi ìtumọ̀ rẹ̀ pamọ́ fún wọn, kí ó má baà yé wọn. Ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí.

46. Àríyànjiyàn kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lórí pé ta ló ṣe pataki jùlọ láàrin wọn.

47. Jesu mọ ohun tí wọn ń rò lọ́kàn. Ó bá mú ọmọde kan, ó gbé e dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

48. Ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọde yìí ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Nítorí ẹni tí ó kéré jùlọ ninu yín, òun ló jẹ́ eniyan pataki jùlọ.”

49. Johanu sọ fún un pé, “Ọ̀gá, a rí ẹnìkan tí ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. A fẹ́ dá a lẹ́kun nítorí kì í ṣe ara wa.”

50. Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé. “Ẹ má dá a lẹ́kun, nítorí ẹni tí kò bá lòdì si yín, tiyín ní ń ṣe.”

Luku 9