Luku 7:41-45 BIBELI MIMỌ (BM)

41. Jesu ní, “Àwọn meji kan jẹ gbèsè. Wọ́n yá owó lọ́wọ́ ẹnìkan tí í máa ń yá eniyan lówó pẹlu èlé. Ọ̀kan jẹ ẹ́ ní àpò marun-un owó fadaka, ekeji jẹ ẹ́ ní aadọta owó fadaka.

42. Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà ati san gbèsè wọn, ẹni tí ó yá wọn lówó bùn wọ́n ní owó náà. Ninu àwọn mejeeji, ta ni yóo fẹ́ràn rẹ̀ jù?”

43. Simoni dáhùn pé, “Ẹni tí ó fún ni owó pupọ ni.”Jesu wá sọ fún un pé, “O wí ire.”

44. Jesu bá yipada sí obinrin náà, ó sọ fún Simoni pé, “Ṣé o rí obinrin yìí? Mo wọ ilé rẹ, o kò fún mi ní omi kí n fi fọ ẹsẹ̀. Ṣugbọn obinrin yìí fi omijé rẹ̀ fọ ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún.

45. O kò fi ìfẹnukonu kí mi. Ṣugbọn obinrin yìí kò dẹ́kun láti fi ẹnu kan ẹsẹ̀ mi láti ìgbà tí mo ti wọ ilé.

Luku 7