Luku 6:9-14 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Jesu wá sọ fún wọn pé, “Mo bi yín, èwo ni ó bá òfin mu, láti ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là, tabi láti pa á run?”

10. Ó wá wo gbogbo wọn yíká, ó sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò.

11. Inú wọn ru sókè, wọ́n wá ń bá ara wọn jíròrò nípa ohun tí wọn ìbá ṣe sí Jesu.

12. Ní ọjọ́ kan, Jesu lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura. Gbogbo òru ni ó fi gbadura sí Ọlọrun.

13. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó yan àwọn mejila ninu wọn, tí ó pè ní aposteli.

14. Àwọn ni Simoni tí ó sọ ní Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filipi ati Batolomiu,

Luku 6