24. Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan ni,” ó bá sọ fún arọ náà pé, “Mo sọ fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.”
25. Lẹsẹkẹsẹ ó dìde lójú gbogbo wọn, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọrun lógo.
26. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan. Wọ́n ń yin Ọlọrun lógo. Ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ń sọ pé, “Ìròyìn kò tó àfojúbà ni ohun tí a rí lónìí!”