4. Bí ó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ẹẹmeje ní ọjọ́ kan, tí ó yipada sí ọ lẹẹmeje, tí ó bẹ̀ ọ́ pé, ‘Jọ̀ọ́ má bínú,’ dáríjì í.”
5. Àwọn aposteli sọ fún Oluwa pé, “Bù sí igbagbọ wa!”
6. Oluwa sọ fún wọn pé, “Bí ẹ bá ní igbagbọ tí ó kéré bíi wóró musitadi tí ó kéré jùlọ, bí ẹ bá wí fún igi sikamore yìí pé, ‘Hú kúrò níbí tigbòǹgbò- tigbòǹgbò, kí o lọ hù ninu òkun!’ Yóo ṣe bí ẹ ti wí.
7. “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní iranṣẹ kan tí ó lọ roko tabi tí ó lọ tọ́jú àwọn aguntan, tí ó bá wọlé dé láti inú oko, ǹjẹ́ ohun tí yóo sọ fún un ni pé kí ó tètè wá jókòó kí ó jẹun?