1. Ní àkókò náà gan-an, àwọn kan sọ fún un nípa àwọn ará Galili kan tí Pilatu pa bí wọ́n ti ń rúbọ lọ́wọ́.
2. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ rò pé àwọn ará Galili wọnyi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo ará Galili yòókù lọ ni, tí wọ́n fi jẹ irú ìyà yìí?
3. Rárá o! Mò ń sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.
4. Tabi àwọn mejidinlogun tí ilé-ìṣọ́ gíga ní Siloamu wólù, tí ó pa wọ́n, ṣé ẹ rò pé wọ́n burú ju gbogbo àwọn eniyan yòókù tí ó ń gbé Jerusalẹmu lọ ni?
5. Rárá ó! Mo sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.”
6. Ó wá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Ẹnìkan gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sinu ọgbà rẹ̀. Ó dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, ṣugbọn kò rí.
7. Ó wá sọ fún olùtọ́jú ọgbà pé, ‘Ṣé o rí i! Ó di ọdún mẹta tí mo ti ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí tí n kò rí. Gé e lulẹ̀. Kí ló dé tí yóo kàn máa gbilẹ̀ lásán?’
8. Ṣugbọn olùtọ́jú ọgbà dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, fi í sílẹ̀ ní ọdún yìí, kí n walẹ̀ yí i ká, kí n bu ilẹ̀dú sí i.
9. Bí ó bá so èso ní ọdún tí ń bọ̀, ó dára. Bí kò bá so èso, gé e.’ ”