47. “Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó bá mọ ohun tí oluwa rẹ̀ fẹ́, ṣugbọn tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ìfẹ́ oluwa rẹ̀ yóo jìyà pupọ.
48. Ṣugbọn èyí tí kò bá mọ̀, tí ó bá tilẹ̀ ṣe ohun tí ó fi yẹ kí ó jìyà, ìyà díẹ̀ ni yóo jẹ. Nítorí ẹni tí a bá fún ní nǹkan pupọ, nǹkan pupọ ni a óo retí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹni tí a bá sì fi nǹkan pupọ ṣọ́, nǹkan pupọ ni a óo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
49. “Iná ni mo wá sọ sí ayé. Ìbá ti dùn tó bí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jó!
50. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi. Ara mi kò lè balẹ̀ títí yóo fi kọjá.
51. Ẹ má ṣe rò pé alaafia ni mo mú wá sí ayé. Bẹ́ẹ̀ kọ́, ará! Mò ń sọ fun yín, ìyapa ni mo mú wá.
52. Láti ìgbà yìí, ẹni marun-un yóo wà ninu ilé kan, àwọn mẹta yóo lòdì sí àwọn meji; àwọn meji yóo lòdì sí àwọn mẹta.