Luku 1:78-80 BIBELI MIMỌ (BM)

78. nítorí àánú Ọlọrun wa,nípa èyí tí oòrùn ìgbàlà fi ràn lé wa lórí láti òkè wá,

79. láti tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tí ó wà ní òkùnkùnati àwọn tí ó jókòó níbi òjìji ikú,láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà alaafia.”

80. Ọmọ náà ń dàgbà, ó sì ń lágbára sí i lára ati lẹ́mìí. Ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni ó ń gbé títí di àkókò tí ó fara han àwọn eniyan Israẹli.

Luku 1