Luku 1:58-63 BIBELI MIMỌ (BM)

58. Àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gbọ́ pé Oluwa ti ṣàánú pupọ fún un, wọ́n wá bá a yọ̀.

59. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá láti kọ́ ọmọ náà ní ilà-abẹ́. Wọ́n fẹ́ sọ ọ́ ní Sakaraya, bí orúkọ baba rẹ̀.

60. Ṣugbọn ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Rárá o! Johanu ni a óo máa pè é.”

61. Wọ́n sọ fún un pé, “Kò sí ẹnìkan ninu àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí ó ń jẹ́ orúkọ yìí.”

62. Wọ́n wá ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀ pé báwo ni ó fẹ́ kí á máa pe ọmọ náà.

63. Ó bá bèèrè fún nǹkan ìkọ̀wé, ó kọ ọ́ pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu ya gbogbo eniyan.

Luku 1