Lefitiku 8:31-36 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Mose bá sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin pé, “Ẹ lọ bọ ẹran àgbò náà lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀, pẹlu burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n ọrẹ ẹbọ ìyàsímímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé: ‘Aaroni ati ọmọ rẹ̀ ni kí wọ́n máa jẹ ẹ́’.

32. Ohunkohun tí ó bá kù ninu ẹran ati burẹdi náà, ẹ dáná sun ún.

33. Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà fún ọjọ́ meje títí tí ọjọ́ ètò ìyàsímímọ́ yín yóo fi pé; nítorí ọjọ́ meje gbáko ni ètò ìyàsímímọ́ yín yóo gbà.

34. Gbogbo bí a ti ṣe lónìí ni OLUWA pa láṣẹ pé kí á ṣe, láti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.

35. Lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ni kí ẹ wà tọ̀sán-tòru fún ọjọ́ meje, kí ẹ máa ṣe àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ fun yín, kí ẹ má baà kú; nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó pa á láṣẹ fún mi.”

36. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ láti ẹnu Mose.

Lefitiku 8